Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – maa n ṣe adua lọpọlọpọ pẹ̀lú àwọn adua ṣókí tí o ko nǹkan ti o pọ sinu, ninu rẹ ni: «Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná» Ó ko oore ayé sínú, bíi ìpèsè arisiki ti o rọrun ti o gbooro, ti o jẹ alaali, ati ìyàwó ti o daa, ati ọmọ itutu ojú, ati ìsinmi, ati ìmọ̀ tí ó wúlò, ati iṣẹ́ rere, àti ohun tí ó jọ ìyẹn ninu awọn ohun ti èèyàn n fẹ ati ohun ti wọn ṣe ni ẹtọ, ati daadaa alukiyaamọ bii lila nibi awọn iya sàréè, ati ibuduro ni ọjọ igbende, ati iná, ati riri iyọnu Ọlọhun, ati nini idẹra gbere, ati isunmọ Oluwa Ajọkẹ-aye.