explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju awọn malaika o nii wa pẹlu ikọ arin irin-ajo kan ti aja n bẹ pẹlu wọn, tabi agogo ti wọn maa n gbe kọ ọrun awọn ẹranko ti wọn maa n gùn ti yio maa mu ohun wa ti o ba ti n lọ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Kikọ kuro nibi nini awọn aja ati mimaa mu wọn lọ si ibi kan, wọn wa yọ kúrò ninu kikọ yii aja ọdẹ tabi aja oluṣọ.
  • Awọn malaika ti wọn o kọ lati wa pẹlu rẹ ni awọn malaika ikẹ, ṣugbọn awọn malaika oluṣọ awọn o ki n ya awọn ẹrusin ni ile ni tabi ni ajo.
  • Kikọ kuro nibi agogo; nítorí pé feere kan ni ninu awọn feere satani, o si tun jọ agogo awọn Kristẹni.
  • O jẹ dandan fun musulumi ki o jina si gbogbo nkan ti o ba jẹ pe o le maa le awọn malaika jina si i.